Sagogo nju
Okun mo losun kun molata
Oribiti Apelunda Solukue
Abanise mase banise mo
Osun mo sile sunmo eni
Igi meta ona ilare
Bi idi baba odi obadi
Ki ire baba ore obare
Bi ologun sese ba dari so o/ o daso
Oni ilare nfobi kan
Oloriburuku nfoju di
Nle o, Olodo Tunbumbi
Ogborun lokun, ajiwunmi bi omo
Oke ilare ko jugun, aje lo ngbeni gun
Omo Ogboru keke fo isa Olori
Omo Ladejokun, Ojire loni o.